Leviticus 6:24-26

Òfin ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀

24 Olúwa sọ fún Mose pé: 25“Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ Ọkùnrin: ‘Wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí ẹ sì pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú Olúwa, níbi tí ẹ ti ń pa ẹran ẹbọ sísun, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ. 26Àlùfáà tó rú ẹbọ náà ni kí ó jẹ ẹ́, ibi mímọ́ ni kí ó ti jẹ ẹ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé.
Copyright information for YorBMYO